OLORI ijo t’ orun Lyrics in Yoruba (Hymn)

Lyrics of OLORI ijo t’ orun

music lyrics

OLORI ijo t’ orun Lyrics

OLORI ijo t’ orun,
L’ ayo l’ a wole fun O;
K’ o to de, ijo t’ aiye,
Y’o ma korin bi t’ orun,
A gbe okan wa s’ oke,
N’ ireti t’ o n’ ibukun;
Awa kigbe, awa f’ iyin
F’ Olorun igbala wa

Bi a wa ninu ‘ponju,
T’ a nkoja ninu ina,
Orin ife l’ awa o ko.
Ti o mu wa sunmo O;
Awa sape, a si yo,
Ninu ojurere Re
Ile t’ o so wa di Tire,
Y’o pa wa mo titi lai

Iwo mu awon enia Re
Koja isan idanwo;
A ki o beru wahala,
‘Tori O wa nitosi,
Aiye, ese at’ Esu,
Kojuja si wa lasan,
L’ agbara Re, a o segun,
A o si ko ‘rin Mose

Awa f’ igbagbo r’ ogo,
T’ O nfe lati fi wa si,
A kegan ere aiye,
Ti a fi siwaju wa,
Bi O ba si ka wa ye,
Awa pelu Stefen t’o ku
Y’o ri O bi o ti duro
Lati pe wa lo s’ oru

Do you find Meevic useful? Click here to give us five stars rating!

YOU MAY LIKE

  1. No related posts available.

Drop Your Comment (0)

No comments yet, be the first to comment!